Skip to main content

Ìtàn ayé Aposteli Timothy Obadare: Afọ́jú oníwàásù tó wo ọ̀pọ̀ sàn lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ ìkọ́ ní Iléṣà

Ìtàn ayé Aposteli Timothy Obadare: Afọ́jú oníwàásù tó wo ọ̀pọ̀ sàn lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ ìkọ́ ní Iléṣà

Aworan Apostle Obadare

ORÍṢUN ÀWÒRÁN, FACEBOOK/APOSTLEDRTOOBADARE

Iwaasu Kristẹni lode oni ti kọja iwaasu itagbangba, ori redio tabi lori ẹrọ amohunmaworan.

Lori ayelujara Facebook Twitter ati Instagram, awọn oniwaasu ti n ba awọn eeyan sọrọ Ọlọrun nigbakugba.

Igbiyanju awọn oniwaasu agba to ti ṣaaju ni ilẹ Yoruba lo jẹ bi atọna fun awọn to wa gba iṣẹ naa lọwọ wọn loni.

Ninu awọn ti o fi ẹsẹ iwaasu lelẹ nilẹ Yoruba ni Aposteli Timothy Obadare wa.

Bi ẹ ba ti n gbọ gbolohun ''ogo ni fun Oluwa ni oke orun! mo tun wi leekan si pe... Ogo ni fun Oluwa ni Oke Orun...E jeki a gbadura '' ẹ o ti mọ pe Oniwaasu Timothy Obadare lo n sọrọ yẹn.

Pupọ eeyan lo jẹri sii pe Aposteeli Obadare jẹ oniwaasu to yatọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ.

Ohun akọkọ to ṣeni ni eemọ nipa Obadare to jẹ ọmọ bibi ilu Ilesa ni pe o ni ipenija oju. 

Ni soki, afọju ti ko rina rara nii ṣe.

Aworan Apostle Obadare

ORÍṢUN ÀWÒRÁN, FACEBOOK/APOSTLEDRTOOBADARE

Oju ita Obadare to fọ deba lẹyin to lugbadi ajakalẹ aarun Ṣọpọnna nigba to wa lọmọdun mẹfa. 

Sibẹ sibẹ, ipenija oju yi ko ni ko ma gbe nkan rere ṣe laye rẹ.

Ọdun 1953 ni Obadare bẹrẹ iṣẹ iwaasu ninu ijọ Aposteli, The Apostolic Church of Nigeria eyi to fi tọ ipasẹ baba rẹ to jẹ Pasitọ ninu ijọ naa.

Laarin ọdun 1953-1957, o ṣiṣẹ takuntakun nipa iwaasu labẹ ijọ yi.


Àkọlé fídíò, 

Mo dúpẹ́ pé ìgbà tí mo wà nínú Jesu ni mo lọ sẹ́wọ̀n, tó bá jẹ́ pé mo wà nínú áyé ni ... - Wòlìí Genesis

A tun ri ka wipe Aposteli Joseph Ayodele Babalola lo mu Obadare wọ inu ijọ Christ Apostolic Church lọdun 1957.

Ipa ribiribi to ko ninu ijọ yi lo mu ki wn pẹka lawn orileede Afrika mii koda wọn tun pẹka de ilẹ okere.

Obadare pada ya kuro ninu ijọ naa lati lọ da ile ijọsin tirẹ silẹ to pe orukọ rẹ ni World Soul Winning Evangelistic Ministry.

Pupọ awọn iwe akọsilẹ sọ pe ọdun 1930 ni wọn bi Obadare ṣugbọn eyi taa mọ ni pe o bẹrẹ ẹkọ nileẹkọ alakọbẹrẹ Apostolic Church Primary School Ise Ilesa ṣugbọn ko pari ẹkọ nibẹ.

Ninu awọn nkan to ṣeni ni kayefi nipa Obadare ni pe ọpọ eeyan lo jẹri pe awọn ri iwosan gba lọwọ rẹ botilẹ jẹ wi pe Obadare gaan fun ara rẹ ko ribi ṣe nkankan si oju rẹ to fọ.

Àkọlé fídíò, 

'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

Biba lero maa n pe sibi iwaasu ti Obadare maa n ṣe loṣooṣu ti o pe akori rẹ ni Koṣeunti eyi to bẹrẹ si ni ṣe lọdun 1970.

Koda lori ẹrọ redio, awọn eeyan a maa sare lọ sile lati lọ gbọ iwaasu rẹ nigba naa lọhun.

Àkọlé fídíò, 

Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Lara awọn itan manigbagbe nipa iṣẹ iyanu ti Obadare maa n ṣe nigba naa leleyi to waye nigba to wa ni kekere.

Gẹgẹ bi a ti ṣe gbọ, Obadare gbagbọ wipe ẹmi mimọ loun le fi gbe iṣẹ Ọlọrun ga. 

Nitorinaa, o sọ pe ki mama rẹ ti oun mọ inu iyara nibi to si ti bẹrẹ si ni gba awẹ kikan kikan.


Àkọlé fídíò, 

'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

Nigba to pe ọjọ kaarun to wa ni inu ile, Ọlọrun yọ si. Ni ọjọ Keje to jade sita, a gbọ pe taara ile ijọsin lo gba lọ.

Nibẹ lo ti ṣe iwaasu wakati mẹrin gbako lati ago mẹwaa titi di ago mejila ọsan.

Nibi iwaasu yi la ti gbọ pe eeyan ọọdunrun le ni aadọta ti ri iwosan gba lọwọ ajakalẹ aarun ikọ to bẹ silẹ nigba taa n wi yi ni ilu Ilesa.

Aworan Apostle Obadare

ORÍṢUN ÀWÒRÁN, RashTv /APOSTLEDRTOOBADARE

Aposteli Obadare jẹ ilumọọka oniwaasu ti o si ṣe ọpọ irinajo nile ati lẹyin odi.

Ni ọpọ ibi to ti maa n ṣe iwaasu, Obadare a maa fi ọrọ Ọlọrun jagun pẹlu awọn ẹmi okunkun ti a si tun maa ṣe itusilẹ fawọn araalu.

Àkọlé fídíò, 

Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò

Lẹyin Aposteli Babalola, ko fẹẹ si oniwaasu ijọ Aposteli to lamilaaka bi Obadare.

Okiki ati igbagbọ tawọn eeyan ni ninu Obadare ṣebi ẹni da wahala di silẹ laarin ijọ CAC ati ijọ rẹ to pe orukọ rẹ ni WOSEM.

Ko si sẹyin bi awọn to ba ti n gbọ iwaasu rẹ ṣe maa n ri ara wọn gẹgẹ bi ọmọ ijọ WOSEM bo ti lẹ jẹ pe abẹ asia CAC ni Obadare ti bẹrẹ.

Aworan Apostle Obadare

ORÍṢUN ÀWÒRÁN, Rashtv APOSTLEDRTOOBADARE

Toun ti bẹ,akọsilẹ fi han pe Obadare gba aṣẹ lọdọ awọn aṣaaju CAC ki o to da ijọ rẹ silẹ.

Nigba ti ọlọjọ yoo fi de ni ọdun 2013, Obadare ti fi ẹsẹ iwaasu lori ẹrọ amounmaworan ati lori redio rinlẹ laarin awọn ẹlẹsin Kristẹni Naijiria.

O jade laye lẹni ọdun mẹtalelọgrin. Obadare fi iyawo kan silẹ lọ ati ọmọ mẹfa ati ọpọ ọmọọmọ.

Àkọlé fídíò, 

Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Comments

Popular posts from this blog

History of Dutse Palace

ACTRESS NIKE PELLER VISITS AARE ONAKAKANFO OF YORUBA LAND- IBA GANI ADAMS IN LAGOS.

Cryptography